Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lè yí àwùjọ rẹ padà.

George ń kà ìwé mímọ́ fún àwọn ọmọ kékeré

Ní Kẹ́ńyà, Kibera jẹ́ ọ̀kan lára àwọn agbègbè aláìní tí ó tóbi jùlọ ní àgbáyé. Ìgbésí ayé lè dàbí èyí tí kò ṣeé ṣe. Ọjọ́ kọ̀ọ̀kan jẹ́ ìpèníjà, ọ̀pọ̀ ni kò sì rí ọ̀nà àbáyọ.

Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lè yí àwùjọ rẹ padà.

“Àwọn ènìyàn ń ṣe àfẹ́rí ìrètí gidigidi. Wọ́n níílò Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, ṣùgbọ́n wọn kò ní ẹnikẹ́ni tí ó lè sọ fún wọn. Ìdí nìyìí tí mo yàn láti wà níbí.”

George, Kẹ́ńyà

George dá ilé ẹ̀kọ́ kan sílẹ̀ ní Kibera láti ran àwọn ọmọdé lọ́wọ́ láti kẹ́kọ̀ọ́. Ó sì tún rí ọ̀nà láti fún wọn ní ohun mìíràn—àǹfààní sí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run nípasẹ̀ Ohun-èlò Bíbélì Ṣékélé.

A ṣe ohun èlò yìí fún àwọn ibi bí Kibera, kí àwọn ènìyàn lè rí Bíbélì kà, kí wọ́n sì lè lò ó láìsí ìtakùn ayélujára.

Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lè yí àwùjọ rẹ padà.

Ní báyìí, George ń pín Ohun-èlò Bíbélì Ṣékélé fún gbogbo ẹni tí ó wà ní àyíká rẹ̀, ó sì ń yí gbogbo àwùjọ rẹ̀ padà!

“Mo ń pín Bíbélì fún gbogbo ènìyàn tí mo mọ̀. Ó ti ń tàn káàkiri báyìí. Àwùjọ ń yípadà nítorí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.”

Ṣe àmúlò Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run láìsí ìkànnì ayélujára, ní ibikíbi, ní ìgbàkúùgbà pẹ̀lú Ohun-èlò Bíbélì Ṣékélé.

Ní ìrírí Ohun-èlò Bíbélì Ṣékélé

Share this post:

Ìfìwéránṣẹ́ yí tún wà ní: Gẹ̀ẹ́sì Èdè Afrikaans Èdè Indonesia Èdè Filipino (Tagalog) Faransé Èdè Ìtàló Èdè Dutch Èdè Pọtugí Èdè Romanian Èdè Rọ́síà Èdè Japaní Èdè China (Èyí tó rọrùn) Èdè China (ìbílẹ̀) Èdè Korea Èdè Lárúbáwá Èdè Belarusian Èdè Bengali Èdè Bulgaria Èdè Danish Èdè Finnish Gíríkì Hébérù Èdè Hindi Èdè Hungary Èdè Malay Èdè Mongolian Èdè Nepali Èdè Norwegian Pẹ́rúsì Èdè Polish Èdè Pọtugí (Potugal) Èdè Slovak Èdè Swahili Èdè Swedish Èdè Tamil Èdè Telugu Èdè Thai Èdè Turkish Èdè Ukarain Èdè Urdu Èdè Vietnamese Èdè Zulu Èdè Czech Èdè Khmer Èdè Malayali Èdè Burmese Èdè Lithuania Èdè Macedónìà Èdè Burmese (Zawgyi) Èdè Serbia Armenian Èdè Icelandic Èdè Croatia Èdè Albania Èdè Welsh Èdè Catalan Èdè Latvia Èdè Haitian Creole Shona Èdè Sorani Kurdish Èdè Xosa