Òtítọ́ ń wá ọ̀nà dé àwọn ibi tí a kò retí.

George ń kà ìwé mímọ́ fún àwọn ọmọ kékeré

Pẹ̀lú àwọn ènìyàn tí ó lé ní 700,000, Kibera ní Kẹ́ńyà jẹ́ ọ̀kan lára àwọn agbègbè òtòṣì tí ó tóbi jùlọ ní àgbáyé.

Ìgbésí ayé níbí lè dà bí ohun tí kò ṣeé ṣe. Ojoojúmọ́ ní ń mú àwọn ìṣòro rẹ̀ wá—láti rí oúnjẹ jẹ, láti tọ́jú ìdílé, àti kí ènìyàn kàn wulẹ̀ tẹ̀síwájú. Ọ̀pọ̀ ni kò rí ọ̀nà àbáyọ.

Òtítọ́ ń wá ọ̀nà dé àwọn ibi tí a kò retí.

“Àwọn ènìyàn ń ṣe àfẹ́rí ìrètí gidigidi. Wọ́n níílò Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, ṣùgbọ́n wọn kò ní ẹnikẹ́ni tí ó lè sọ fún wọn. Ìdí nìyìí tí mo yàn láti wà níbí.”

George, Kẹ́ńyà

George dá ilé ẹ̀kọ́ kan sílẹ̀ ní Kibera láti ran àwọn ọmọdé lọ́wọ́ láti kẹ́kọ̀ọ́. Ó sì tún rí ọ̀nà láti fún wọn ní ohun mìíràn—àǹfààní sí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run nípasẹ̀ Ohun-èlò Bíbélì Ṣékélé.

A ṣe àkànṣe ohun-èlò yìí tí kò níílò ìkànnì ayélujára fún àwọn agbègbè bíi Kibera, kí àwọn ènìyàn lè rí Bíbélì kà kí wọ́n sì jinlẹ̀ nínú rẹ̀ ní ibikíbi, ní ìgbàkúùgbà.

Òtítọ́ ń wá ọ̀nà dé àwọn ibi tí a kò retí.

Ní báyìí, George ń pín Ohun-èlò Bíbélì Ṣékélé fún gbogbo ẹni tí ó wà ní àyíká rẹ̀, ó sì ń yí gbogbo àwùjọ rẹ̀ padà!

“Mo ń pín Bíbélì fún gbogbo ẹni tí mo mọ̀. Ní báyìí ó ń tàn ká ibi gbogbo. Àwùjọ ń yípadà nítorí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.”

Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ń dé orílẹ̀-èdè gbogbo, ẹ̀yà gbogbo, àti ènìyàn gbogbo. Bí o ṣe ń ṣe àjọyọ̀ ohun tí Ọlọ́run ń ṣe ní gbogbo àgbáyé, ronú lórí Ìfihàn 7.

Ka Ìfihàn 7

Share this post:

Ìfìwéránṣẹ́ yí tún wà ní: Gẹ̀ẹ́sì Èdè Afrikaans Èdè Indonesia Èdè Filipino (Tagalog) Faransé Èdè Ìtàló Èdè Dutch Èdè Pọtugí Èdè Romanian Èdè Rọ́síà Èdè Japaní Èdè China (Èyí tó rọrùn) Èdè China (ìbílẹ̀) Èdè Korea Èdè Lárúbáwá Èdè Belarusian Èdè Danish Gíríkì Hébérù Èdè Hindi Èdè Hungary Èdè Malay Èdè Mongolian Èdè Nepali Èdè Norwegian Pẹ́rúsì Èdè Polish Èdè Pọtugí (Potugal) Èdè Swahili Èdè Tamil Èdè Telugu Èdè Thai Èdè Turkish Èdè Ukarain Èdè Urdu Èdè Vietnamese Èdè Zulu Èdè Khmer Èdè Burmese Èdè Lithuania Èdè Serbia Armenian Èdè Icelandic Èdè Croatia Èdè Albania Èdè Welsh Èdè Catalan Èdè Latvia Èdè Haitian Creole Shona Èdè Sorani Kurdish Èdè Xosa