Ṣàwárí àwọn ohun èlò Bíbélì wọ̀nyí ní àkókò Oṣù Bíbélì Àgbáyé…

Ṣe Àjọyọ̀ Oṣù Bíbélì Àgbáyé

Ǹjẹ́ o mọ̀ pé YouVersion ní Àwọn Àgbáríjọ Ohun Èlò Bíbélì? Láti àwọn ọmọdé, sí àwọn ọ̀dọ́langba, títí dé àwọn àgbàlagbà—olúkúlùkù ló ń kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ní ọ̀nà tí ó yàtọ̀. Ìdí nìyìí tí a fi ṣẹ̀dá àwọn ohun èlò tí a gbé kalẹ̀ fún àwọn ènìyàn ní onírúurú ẹ̀ka àwùjọ àti agbègbè.

Ṣàwárí ohun èlò Bíbélì tí ó dára jùlọ fún ọ!

À ń ṣe àfihàn: Òbìrípo Bíbélì

Òbìrípo Bíbélì ni ọmọ ẹgbẹ́ tuntun àyánrán nínú Àgbáríjọ Àwọn Ohun Èlò wa! A ṣẹ̀dá Òbìrípo Bíbélì fún àwọn ọ̀dọ́langba láti pèsè àwọn ìgbòkègbodò amóríyá, àbúdà ìbáraẹnisọ̀rọ̀, àti àwọn eré tí yóò ràn wọ́n lọ́wọ́ láti há Ìwé Mímọ́ sórí, kí wọ́n sì máa rántí rẹ̀. Tí ìwọ bá jẹ́ ọ̀dọ́langba, tàbí tí o bá ní ọ̀kan nínú ayé rẹ, o kò ní fẹ́ pàdánù èyí.

App Store | Google Play

Ohun èlò Bíbélì fún Àwon Ọmọdé

Ohun èlò yìí wà fún àwọn ọmọ kékeré tí ó wà nínú ayé rẹ. Nínú Ohun Èlò Bíbélì fún Àwọn Ọmọdé, ìwọ yóò ṣàwárí àwọn ìtàn Bíbélì tí ó w’ọni lọ́kàn àti àwọn eré ìdárayá tí a ṣe láti ran àwọn ọmọdé lọ́wọ́ láti nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run àti Ọ̀rọ̀ Rẹ̀.

App Store | Google Play

Ohun èlò Bíbélì

Èyí ni Ohun Èlò Bíbélì #1 tí à gba sílẹ̀ jùlọ ní àgbàáyéaA! Pẹ̀lú àǹfààní sí ẹ̀dà ìtumọ̀ Bíbélì tí ó lé ní 3,500, ní èdè 2,300, àti ẹgbẹẹgbẹ̀rún Ètò Bíbélì, kò tíì rọrùn bí èyí rí láti lo àkókò nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ní ọ̀nà tí ó bá ọ mu.

App Store | Google Play

Ohun-èlò Bíbélì Ṣékélé

Ohun-èlò Bíbélì Alábọ́ọ́dé ń jẹ́ kí o ní ìrírí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run láìlo ìtàkùn ìsopọ̀ ayélujára, ní ibikíbi àti ní ìgbàkígbà. Ohun èlò yìí wà ní àwọn agbègbè tí a ṣà yàn.

Google Play

Kópa nínú Ìpèníjà Ọjọ́ 30 nípa ṣíṣàgbàsílẹ̀ ọ̀kan nínú àwọn Ohun Èlò wọ̀nyí! Àti pé, bẹ̀rẹ̀ láti ọjọ́ kìíní Oṣù kọkànlá, máa lo Ohun Èlò Bíbélì fún ọgbọ̀n ọjọ́ 30 léraléra, kí o sì jèrè Àmì-ẹ̀yẹ àkànṣe Oṣù Bíbélì Àgbáyé.

Dara pọ̀ Mọ́ Wa Báyìí

Share this post:

Ìfìwéránṣẹ́ yí tún wà ní: Gẹ̀ẹ́sì Èdè Afrikaans Èdè Indonesia Jamaní Èdè Sípénì Èdè Filipino (Tagalog) Faransé Èdè Ìtàló Èdè Dutch Èdè Pọtugí Èdè Romanian Èdè Rọ́síà Èdè Japaní Èdè China (Èyí tó rọrùn) Èdè China (ìbílẹ̀) Èdè Korea Èdè Lárúbáwá Èdè Belarusian Èdè Bengali Èdè Bulgaria Èdè Danish Èdè Finnish Gíríkì Hébérù Èdè Hindi Èdè Hungary Èdè Malay Èdè Mongolian Èdè Nepali Èdè Norwegian Èdè Polish Èdè Pọtugí (Potugal) Èdè Slovak Èdè Swahili Èdè Swedish Èdè Tamil Èdè Thai Èdè Ukarain Èdè Urdu Èdè Vietnamese Èdè Zulu Èdè Czech Èdè Khmer Èdè Malayali Èdè Sípénì (Spain) Èdè Lithuania Èdè Macedónìà Èdè Burmese (Zawgyi) Èdè Serbia Armenian Èdè Icelandic Èdè Croatia Èdè Albania Èdè Welsh Èdè Catalan Èdè Latvia Èdè Haitian Creole Shona Èdè Sorani Kurdish Èdè Xosa