Ní ìgbà tí ìrètí dàbí ohun tí kò ṣeé ṣe, Ọlọ́run pàdé Álísìì.

Ìkìlọ̀ nípa àkóónú: ìtàn tí ó tẹ̀lé e ní àwọn kókó nípa ṣíṣe ara ẹni léṣe àti ìsoríkọ́ tí ó lè kó ìdààmú bá àwọn òǹkàwé kan.

Ní ìgbà tí ìrètí dàbí ohun tí kò ṣeé ṣe, Ọlọ́run pàdé Álísìì.

Ní ìgbà tí Álísìì pé ọmọ ọdún mẹ́rìndínlógún, ó rí ara rẹ̀ nínú ìgbèkùn ìrora àti àdánù, ìsoríkọ́ àti ìdáwà sì borí rẹ̀.

Pẹ̀lú bí ipó àìnírètí rẹ̀ ṣe ń peléke sí i, ní alẹ́ ọjọ́ kan ó pinnu láti gba ẹ̀mí ara rẹ̀. Ìgbà náà ni ohun tí kò ṣeé ṣàlàyé ṣẹlẹ̀.

Ní etí ìlékè fèrèsé ilé alájà gíga gogoro tí ó ń gbé, ẹ̀fúùfù líle kan fẹ́ lójijì, ó sì mú u ṣubú sẹ́yìn wọ inú yàrá rẹ̀ dípò kí ó ṣubú síwájú.

Bí ó ṣe dùbúlẹ̀ lórí ilẹ̀, tí ẹnu yà á, tí ó sì ń sọkún, Álísìì gba àtẹ̀jíṣẹ́ kan láti ọ̀dọ̀ aládùúgbò rẹ̀ tí ó ń pè é sí ilé ìjọsìn. Ó gbà láti lọ, ibẹ̀ sì ni ó ti kọ́kọ́ ṣàwárí Ohun Èlò Bíbélì.

Ní ìgbà tí ìrètí dàbí ohun tí kò ṣeé ṣe, Ọlọ́run pàdé Álísìì.

Ó bẹ̀rẹ̀ Ètò Bíbélì kan. Nípasẹ̀ rẹ̀, ó rí ìrètí, ó sì fi ayé rẹ̀ fún Jésù.

Lónìí, Álísìì ń ṣẹ̀dá, ó sì ń ṣe àtẹ̀jáde àwọn Ètò Bíbélì gẹ́gẹ́ bí alábàáṣiṣẹ́pọ̀ YouVersion nípasẹ̀ ohun èlò kan náà tí ó fi Jésù hàn án. Kì í ṣe pé ìrètí kún inú rẹ̀ nìkan—ó tún ń tan án kálẹ̀.

Ṣé o mọ ẹnìkan ní àyíká rẹ tí ó níílò Ọlọ́run gidigidi? Fi Ohun-èlò Bíbélì hàn án, kí o sì bèèrè pé kí Ọlọ́rùn fi ìrètí kún inú wọn.

Share this post:

Ìfìwéránṣẹ́ yí tún wà ní: Gẹ̀ẹ́sì Èdè Afrikaans Èdè Indonesia Jamaní Èdè Sípénì Èdè Filipino (Tagalog) Faransé Èdè Ìtàló Èdè Dutch Èdè Pọtugí Èdè Romanian Èdè Rọ́síà Èdè Japaní Èdè China (Èyí tó rọrùn) Èdè China (ìbílẹ̀) Èdè Korea Èdè Lárúbáwá Èdè Belarusian Èdè Bengali Èdè Bulgaria Èdè Danish Èdè Finnish Gíríkì Hébérù Èdè Hindi Èdè Hungary Èdè Malay Èdè Mongolian Èdè Nepali Èdè Norwegian Pẹ́rúsì Èdè Polish Èdè Pọtugí (Potugal) Èdè Slovak Èdè Swahili Èdè Swedish Èdè Tamil Èdè Telugu Èdè Thai Èdè Turkish Èdè Ukarain Èdè Urdu Èdè Vietnamese Èdè Zulu Èdè Czech Èdè Khmer Èdè Malayali Èdè Burmese Èdè Lithuania Èdè Macedónìà Èdè Burmese (Zawgyi) Èdè Serbia Armenian Èdè Icelandic Èdè Croatia Èdè Albania Èdè Welsh Èdè Catalan Èdè Latvia Èdè Haitian Creole Shona Èdè Sorani Kurdish Èdè Xosa Igbo Serbian (Latin) Slovenian