Gba Bíbélì ọ̀fẹ́ ti orí ayélujára

Gba Bíbélì ọ̀fẹ́

ti orí ayélujára fún fóònù àti tábúlẹ̀tì


Kà Bíbélì

Máa mú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run dání níbikíbi tó o bá lọ nípa ṣíṣàtìlẹyìn Bíbélì App lọ́fẹ̀ẹ́. Tẹ́tí sí ohùn Bíbélì, ṣe Àdúrà, kẹ́kọ̀ọ́ pẹ̀lú Àwọn Ọ̀rẹ́, àti púpọ̀ sí i fún ọ̀fẹ́.

Kà Bíbélì


Helpful links:
Kà Bíbélì lórí ayélujára – Yoruba

OLUWA ni Olùṣọ́-agutan mi

OLUWA ni Olùṣọ́-agutan mi

1  
OLUWA li Oluṣọ-agutan mi; emi kì yio ṣe alaini.

2  
O mu mi dubulẹ ninu papa-oko tutù; o mu mi lọ si iha omi didakẹ rọ́rọ́.

3  
O tù ọkàn mi lara; o mu mi lọ nipa ọ̀na ododo nitori orukọ rẹ̀.

4  
Nitõtọ, bi mo tilẹ nrìn larin afonifoji ojiji ikú, emi kì yio bẹ̀ru ibi kan; nitori ti Iwọ pẹlu mi; ọgọ rẹ ati ọpá rẹ nwọn ntù mi ninu.

5  
Iwọ tẹ́ tabili onjẹ silẹ niwaju mi li oju awọn ọta mi; iwọ dà ororo si mi li ori; ago mi si kún akúnwọsilẹ.

6  
Nitotọ, ire ati ãnu ni yio ma tọ̀ mi lẹhin li ọjọ aiye mi gbogbo; emi o si ma gbe inu ile Oluwa lailai.


Feti si Orin Dafidi 23

Psalm 23 in Yoruba

Psalm 23 in English

Awa si mọ̀ pe ohun gbogbo li o nṣiṣẹ pọ̀ si rere fun awọn ti o fẹ Ọlọrun

Awa si mọ̀ pe ohun gbogbo li o nṣiṣẹ pọ̀ si rere fun awọn ti o fẹ Ọlọrun

28  
Awa si mọ̀ pe ohun gbogbo li o nṣiṣẹ pọ̀ si rere fun awọn ti o fẹ Ọlọrun, ani fun awọn ẹniti a pè gẹgẹ bi ipinnu rẹ̀.

29  
Nitori awọn ẹniti o ti mọ̀ tẹlẹ, li o si ti yàn tẹlẹ lati ri bi aworan Ọmọ rẹ̀, ki on le jẹ akọbi larin awọn arakunrin pupọ.

30  
Awọn ti o si ti yàn tẹlẹ, awọn li o si ti pè: awọn ẹniti o si ti pè, awọn li o si ti dalare: awọn ẹniti o si ti dalare, awọn li o si ti ṣe logo.

31  
Njẹ kili awa o ha wi si nkan wọnyi? Bi Ọlọrun bá wà fun wa, tani yio kọ oju ija si wa?

32  
Ẹniti kò da Ọmọ on tikararẹ̀ si, ṣugbọn ti o jọwọ rẹ̀ lọwọ fun gbogbo wa, yio ha ti ṣe ti kì yio fun wa li ohun gbogbo pẹlu rẹ̀ lọfẹ?

33  
Tani yio ha kà ohunkohun si ọrùn awọn ayanfẹ Ọlọrun? Ihaṣe Ọlọrun ti ndare?

34  
Tali ẹniti ndẹbi? Ihaṣe Kristi Jesu ti o kú, ki a sa kuku wipe ti a ti ji dide kuro ninu okú, ẹniti o si wà li ọwọ́ ọtun Ọlọrun, ti o si mbẹ̀bẹ fun wa?

35  
Tani yio ha yà wa kuro ninu ifẹ Kristi? ipọnju ni, tabi wahalà, tabi inunibini, tabi ìyan, tabi ìhoho, tabi ewu, tabi idà?

36  
Gẹgẹ bi a ti kọ ọ pe, Nitori rẹ li a ṣe npa wa kú li gbogbo ọjọ; a nkà wa si bi agutan fun pipa.

37  
Ṣugbọn ninu gbogbo nkan wọnyi awa jù ẹniti o ṣẹgun lọ nipa ẹniti o fẹ wa.

38  
Nitori o da mi loju pe, kì iṣe ikú, tabi ìye, tabi awọn angẹli, tabi awọn ijoye, tabi awọn alagbara, tabi ohun ìgba isisiyi, tabi ohun ìgba ti mbọ̀

39  
Tabi òke, tabi ọgbun, tabi ẹda miran kan ni yio le yà wa kuro ninu ifẹ Ọlọrun, ti o wà ninu Kristi Jesu Oluwa wa.


Feti si Rom 8

Romans 8 in Yoruba

Romans 8 in English

Ifẹ a mã mu suru, a si mã ṣeun

Ifẹ a mã mu suru, a si mã ṣeun

4  
Ifẹ a mã mu suru, a si mã ṣeun; ifẹ kì iṣe ilara; ifẹ kì isọrọ igberaga, kì ifẹ̀

5  
Kì ihuwa aitọ́, kì iwá ohun ti ara rẹ̀, a kì imu u binu, bẹ̃ni kì igbiro ohun buburu

6  
Kì iyọ̀ si aiṣododo, ṣugbọn a mã yọ̀ ninu otitọ

7  
A mã farada ohun gbogbo, a mã gbà ohun gbogbo gbọ́, a mã reti ohun gbogbo, a mã fàiyarán ohun gbogbo.

8  
Ifẹ kì iyẹ̀ lai: ṣugbọn biobaṣepe isọtẹlẹ ni, nwọn ó dopin; biobaṣepe ẹ̀bun ahọn ni, nwọn ó dakẹ; biobaṣepe ìmọ ni, yio di asan.

9  
Nitori awa mọ̀ li apakan, awa si nsọtẹlẹ li apakan.

10  
Ṣugbọn nigbati eyi ti o pé ba de, eyi ti iṣe ti apakan yio dopin.

11  
Nigbati mo wà li ewe, emi a mã sọ̀rọ bi èwe, emi a mã moye bi ewe, emi a mã gbero bi ewe: ṣugbọn nigbati mo di ọkunrin tan, mo fi ìwa ewe silẹ.

12  
Nitoripe nisisiyi awa nriran baibai ninu awojiji; ṣugbọn nigbana li ojukoju: nisisiyi mo mọ̀ li apakan; ṣugbọn nigbana li emi ó mọ̀ gẹgẹ bi mo si ti di mimọ̀ pẹlu.

13  
Njẹ nisisiyi igbagbọ́, ireti, ati ifẹ mbẹ, awọn mẹta yi: ṣugbọn eyiti o tobi jù ninu wọn ni ifẹ.


Feti si I Kor 13

1 Corinthians 13 in Yoruba

1 Corinthians 13 in English

Orin Dafidi 91: Ẹniti o joko ni ibi ìkọkọ Ọga-ogo

Ẹniti o joko ni ibi ìkọkọ Ọga-ogo

1  
ẸNITI o joko ni ibi ìkọkọ Ọga-ogo ni yio ma gbe abẹ ojiji Olodumare.

2  
Emi o wi fun Ọlọrun pe, Iwọ li àbo ati odi mi; Ọlọrun mi, ẹniti emi gbẹkẹle.

3  
Nitõtọ on o gbà ọ ninu ikẹkun awọn pẹyẹpẹyẹ, ati ninu àjakalẹ-àrun buburu.

4  
Yio fi iyẹ́ rẹ̀ bò ọ, abẹ iyẹ́-apa rẹ̀ ni iwọ o si gbẹkẹle: otitọ rẹ̀ ni yio ṣe asà ati apata rẹ.

5  
Iwọ kì yio bẹ̀ru nitori ẹ̀ru oru; tabi fun ọfa ti nfo li ọsán

6  
Tabi fun àjakalẹ-àrun ti nrìn kiri li okunkun, tabi fun iparun ti nrun-ni li ọsángangan.

7  
Ẹgbẹrun yio ṣubu li ẹgbẹ rẹ, ati ẹgbarun li apa ọtún rẹ: ṣugbọn kì yio sunmọ ọdọ rẹ.

8  
Kiki oju rẹ ni iwọ o ma fi ri, ti o si ma fi wo ère awọn enia buburu.

9  
Nitori iwọ, Oluwa, ni iṣe ãbo mi, iwọ ti fi Ọga-ogo ṣe ibugbe rẹ.

10  
Buburu kan kì yio ṣubu lu ọ, bẹ̃li arunkarun kì yio sunmọ ile rẹ.

11  
Nitori ti yio fi aṣẹ fun awọn angeli rẹ̀ nitori rẹ, lati pa ọ mọ́ li ọ̀na rẹ gbogbo.

12  
Nwọn o gbé ọ soke li ọwọ́ wọn, ki iwọ ki o má ba fi ẹṣẹ rẹ gbun okuta.

13  
Iwọ o kọja lori kiniun ati pamọlẹ: ẹgbọrọ kiniun ati ejò-nla ni iwọ o fi ẹsẹ tẹ̀-mọlẹ.

14  
Nitori ti o fẹ ifẹ rẹ̀ si mi, nitorina li emi o ṣe gbà a: emi o gbé e leke, nitori ti o mọ̀ orukọ mi.

15  
On o pè orukọ mi, emi o si da a lohùn: emi o pẹlu rẹ̀ ninu ipọnju, emi o gbà a, emi o si bu ọlá fun u.

16  
Ẹmi gigun li emi o fi tẹ́ ẹ lọrun, emi o si fi igbala mi hàn a.


Feti si Orin Dafidi 91

Psalm 91 in Yoruba

Psalm 91 in English

Yoruba Online Bible