OLUWA ni Olùṣọ́-agutan mi

OLUWA ni Olùṣọ́-agutan mi

1  
OLUWA li Oluṣọ-agutan mi; emi kì yio ṣe alaini.

2  
O mu mi dubulẹ ninu papa-oko tutù; o mu mi lọ si iha omi didakẹ rọ́rọ́.

3  
O tù ọkàn mi lara; o mu mi lọ nipa ọ̀na ododo nitori orukọ rẹ̀.

4  
Nitõtọ, bi mo tilẹ nrìn larin afonifoji ojiji ikú, emi kì yio bẹ̀ru ibi kan; nitori ti Iwọ pẹlu mi; ọgọ rẹ ati ọpá rẹ nwọn ntù mi ninu.

5  
Iwọ tẹ́ tabili onjẹ silẹ niwaju mi li oju awọn ọta mi; iwọ dà ororo si mi li ori; ago mi si kún akúnwọsilẹ.

6  
Nitotọ, ire ati ãnu ni yio ma tọ̀ mi lẹhin li ọjọ aiye mi gbogbo; emi o si ma gbe inu ile Oluwa lailai.

Psalm 23 in Yoruba

Psalm 23 in English

CategoriesUncategorized